21. Ẹja ti o wà li odò si kú; odò na si nrùn, awọn ara Egipti kò si le mu ninu omi odò na; ẹ̀jẹ si wà ni gbogbo ilẹ Egipti,
22. Awọn alalupayida Egipti si fi idán wọn ṣe bẹ̃: àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
23. Farao si pada o lọ si ile rẹ̀, kò si fi ọkàn rẹ̀ si eyi pẹlu.
24. Gbogbo awọn ara Egipti si wàlẹ yi odò na ká fun omi mimu; nitoriti nwọn kò le mu ninu omi na.
25. Ọjọ́ meje si pé, lẹhin igbati OLUWA lù odò na.