Eks 37:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si ṣe kerubu wurà meji; iṣẹ lilù li o ṣe wọn, ni ìku mejeji itẹ́-ãnu na;

8. Kerubu kan ni ìku kini, ati kerubu keji ni ìku keji: lati ara itẹ́-ãnu li o ti ṣe awọn kerubu na ni ìku mejeji rẹ̀.

9. Awọn kerubu na si nà iyẹ́-apa wọn soke, nwọn si fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, nwọn si dojukọ ara wọn; itẹ́-ãnu na ni awọn kerubu kọjusi.

10. O si fi igi ṣittimu ṣe tabili kan: igbọnwọ meji ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀, igbọnwọ kan on àbọ si ni giga rẹ̀:

11. O si fi kìki wurà bò o, o si ṣe igbáti wurà si i yiká.

12. O si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, o si ṣe igbáti wurà kan fun eti rẹ̀ yiká.

13. O si dà oruka wurà mẹrin fun u, o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà ni ibi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rẹ̀.

14. Labẹ igbáti na ni oruka wọnni wà, àye fun ọpá lati fi rù tabili na.

15. O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi wurà bò wọn, lati ma rù tabili na.

16. O si ṣe ohunèlo wọnni ti o wà lori tabili na, awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, lati ma fi dà ohun mimu, kìki wurà ni.

17. O si fi kìki wurà, ṣe ọpá-fitila: iṣẹ lilù li o ṣe ọpá-fitila na; ọpá rẹ̀, ati ẹka rẹ̀, ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn:

18. Ẹka mẹfa li o jade ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan rẹ̀, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na, ni ìha keji rẹ̀.

19. Ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka kan, irudi kan ati itanna; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka keji, irudi kan ati itanna: bẹ̃ni li ẹka mẹfẹfa ti o jade lara ọpá-fitila na.

20. Ati ninu ọpá-fitila na li a ṣe ago mẹrin bi itanna almondi, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀:

Eks 37