13. O si dà oruka wurà mẹrin fun u, o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà ni ibi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rẹ̀.
14. Labẹ igbáti na ni oruka wọnni wà, àye fun ọpá lati fi rù tabili na.
15. O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi wurà bò wọn, lati ma rù tabili na.
16. O si ṣe ohunèlo wọnni ti o wà lori tabili na, awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, lati ma fi dà ohun mimu, kìki wurà ni.
17. O si fi kìki wurà, ṣe ọpá-fitila: iṣẹ lilù li o ṣe ọpá-fitila na; ọpá rẹ̀, ati ẹka rẹ̀, ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn:
18. Ẹka mẹfa li o jade ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan rẹ̀, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na, ni ìha keji rẹ̀.
19. Ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka kan, irudi kan ati itanna; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka keji, irudi kan ati itanna: bẹ̃ni li ẹka mẹfẹfa ti o jade lara ọpá-fitila na.
20. Ati ninu ọpá-fitila na li a ṣe ago mẹrin bi itanna almondi, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀:
21. Ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, gẹgẹ bi ẹka mẹfẹfa ti o jade lara rẹ̀.
22. Irudi wọn ati ẹka wọn jẹ bakanna: gbogbo rẹ̀ jẹ́ iṣẹ lilù kìki wurà kan.
23. O si ṣe fitila rẹ̀, meje, ati alumagaji rẹ̀, ati awo rẹ̀, kìki wurà ni.
24. Talenti kan kìki wurà li o fi ṣe e, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀.
25. O si fi igi ṣittimu ṣe pẹpẹ turari: gigùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, ibú rẹ̀ si jẹ́ igbọnwọ kan, ìha mẹrin ọgbọgba; giga rẹ̀ si jẹ́ igbọnwọ meji; iwo rẹ̀ wà lara rẹ̀.
26. O si fi kìki wurà bò o, ati òke rẹ̀, ati ìha rẹ̀ yiká, ati iwo rẹ̀: o si ṣe igbáti wurà si i yiká.