Eks 36:7-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitoriti ohun-èlo ti nwọn ni o to fun gbogbo iṣẹ na, lati fi ṣe e, o si pọ̀ju.

8. Ati olukuluku ọkunrin ọlọgbọ́n ninu awọn ti o ṣe iṣẹ agọ́ na, nwọn ṣiṣẹ aṣọ-tita mẹwa; ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, pẹlu awọn kerubu, iṣẹ-ọnà li on fi ṣe wọn.

9. Ina aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ati ibò aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na jẹ́ ìwọn kanna.

10. O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn: ati aṣọ-tita marun keji li o si solù mọ́ ara wọn.

11. O si pa ojóbo aṣọ-alaró li eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù; bẹ̃ gẹgẹ li o ṣe si ìha eti ikangun aṣọ-tita keji nibi isolù keji.

12. Ãdọta ojóbo li o pa lara aṣọ-tita kan, ati ãdọta ojóbo li o si pa li eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji: ojóbo na so aṣọ-tita kini mọ́ keji.

13. O si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, o si fi ikọ́ wọnni fi aṣọ-tita kan kọ́ ekeji: bẹ̃li o si di odidi agọ́.

14. O si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ fun agọ́ na lori ibugbé na: aṣọ-tita mọkanla li o ṣe wọn.

15. Ìna aṣọ-tita kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ibò aṣọ-tita kan si jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla jẹ́ ìwọn kanna.

16. O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn.

Eks 36