6. Mose si paṣẹ, nwọn si ṣe ki nwọn ki o kede yi gbogbo ibudó na ká, wipe, Máṣe jẹ ki ọkunrin tabi obinrin ki o tun ṣe iṣẹkiṣẹ fun ọrẹ ibi mimọ́ na mọ́. Bẹ̃li a da awọn enia lẹkun ati ma múwa.
7. Nitoriti ohun-èlo ti nwọn ni o to fun gbogbo iṣẹ na, lati fi ṣe e, o si pọ̀ju.
8. Ati olukuluku ọkunrin ọlọgbọ́n ninu awọn ti o ṣe iṣẹ agọ́ na, nwọn ṣiṣẹ aṣọ-tita mẹwa; ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, pẹlu awọn kerubu, iṣẹ-ọnà li on fi ṣe wọn.
9. Ina aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ati ibò aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na jẹ́ ìwọn kanna.
10. O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn: ati aṣọ-tita marun keji li o si solù mọ́ ara wọn.