3. Nwọn si gbà gbogbo ọrẹ na lọwọ Mose, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, lati fi ṣe e. Sibẹ̀ nwọn si nmú ọrẹ ọfẹ fun u wá li orowurọ̀.
4. Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọgbọ́n, ti o ṣe gbogbo isẹ ibi mimọ́ na, lọ olukuluku kuro ni ibi iṣẹ rẹ̀ ti nwọn ṣe;
5. Nwọn si sọ fun Mose pe, Awọn enia múwa pupọ̀ju fun iṣẹ ìsin na, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe.
6. Mose si paṣẹ, nwọn si ṣe ki nwọn ki o kede yi gbogbo ibudó na ká, wipe, Máṣe jẹ ki ọkunrin tabi obinrin ki o tun ṣe iṣẹkiṣẹ fun ọrẹ ibi mimọ́ na mọ́. Bẹ̃li a da awọn enia lẹkun ati ma múwa.
7. Nitoriti ohun-èlo ti nwọn ni o to fun gbogbo iṣẹ na, lati fi ṣe e, o si pọ̀ju.
8. Ati olukuluku ọkunrin ọlọgbọ́n ninu awọn ti o ṣe iṣẹ agọ́ na, nwọn ṣiṣẹ aṣọ-tita mẹwa; ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, pẹlu awọn kerubu, iṣẹ-ọnà li on fi ṣe wọn.
9. Ina aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ati ibò aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na jẹ́ ìwọn kanna.
10. O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn: ati aṣọ-tita marun keji li o si solù mọ́ ara wọn.
11. O si pa ojóbo aṣọ-alaró li eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù; bẹ̃ gẹgẹ li o ṣe si ìha eti ikangun aṣọ-tita keji nibi isolù keji.
12. Ãdọta ojóbo li o pa lara aṣọ-tita kan, ati ãdọta ojóbo li o si pa li eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji: ojóbo na so aṣọ-tita kini mọ́ keji.
13. O si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, o si fi ikọ́ wọnni fi aṣọ-tita kan kọ́ ekeji: bẹ̃li o si di odidi agọ́.
14. O si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ fun agọ́ na lori ibugbé na: aṣọ-tita mọkanla li o ṣe wọn.
15. Ìna aṣọ-tita kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ibò aṣọ-tita kan si jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla jẹ́ ìwọn kanna.
16. O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn.
17. O si pa ãdọta ojóbo si ìha eti ikangun aṣọ-tita na ni ibi isolù, ati ãdọta ojóbo li o si pa si eti aṣọ-tita ti o so ekeji lù.
18. O si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ lati so agọ́ na lù pọ̀, ki o le ṣe ọkan.
19. O si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori eyi.
20. O si ṣe apáko igi ṣittimu fun agọ́ na li ogurodo.