Eks 36:27-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn o ṣe apáko mẹfa.

28. Apáko meji li o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha mejeji.

29. A si so wọn lù nisalẹ, a si so wọn lù pọ̀ li ori rẹ̀, si oruka kan: bẹ̃li o ṣe si awọn meji ni igun mejeji.

30. Apáko mẹjọ li o wà, ihò-ìtẹbọ wọn si jẹ́ ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun ti fadakà; ìtẹbọ mejimeji li o wà nisalẹ apáko kọkan.

31. O si ṣe ọpá igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na,

32. Ati ọpá marun fun apáko ìha keji agọ́ na, ati ọpá marun fun apáko agọ́ na fun ìha ìwọ-õrùn.

33. O si ṣe ọpá ãrin o yọ jade lara apáko wọnni, lati opin ekini dé ekeji.

34. O si fi wurà bò apáko wọnni, o si fi wurà ṣe oruka wọn, lati ṣe ipò fun ọpá wọnni, o si fi wurà bò ọpá wọnni.

35. O si fi aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ṣe aṣọ-ikele: iṣẹ ọlọnà li o fi ṣe e ti on ti awọn kerubu.

36. O si ṣe opó igi ṣittimu mẹrin si i, o si fi wurà bò wọn: kọkọrọ wọn ti wurà ni, o si dà ihò-ìtẹbọ fadakà mẹrin fun wọn.

37. O si ṣe aṣọ-isorọ̀ kan fun ẹnu-ọ̀na Agọ́ na, aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti iṣẹ abẹ́rẹ;

38. Ati opó rẹ̀ mararun ti on ti kọkọrọ wọn: o si fi wurà bò ọnà ori wọn, ati ọjá wọn: ṣugbọn idẹ ni ihò-ìtẹbọ wọn mararun.

Eks 36