22. Apáko kan ni ìtẹbọ meji, nwọn jìna si ara wọn li ọgbọgba; bẹ̃li o ṣe sara gbogbo apáko agọ́ na.
23. O si fi apáko ṣe agọ́ na; ogún apáko ni fun ìha ọtún, si ìha gusù:
24. Ati ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà li o ṣe nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ rẹ̀ meji, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ rẹ̀ meji.
25. Ati fun ìha keji agọ́ na, ti o wà ni ìha ariwa, o ṣe ogún apáko,
26. Ati ogoji ihò-ìtẹbọ wọn ti fadakà; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji.
27. Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn o ṣe apáko mẹfa.
28. Apáko meji li o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha mejeji.
29. A si so wọn lù nisalẹ, a si so wọn lù pọ̀ li ori rẹ̀, si oruka kan: bẹ̃li o ṣe si awọn meji ni igun mejeji.
30. Apáko mẹjọ li o wà, ihò-ìtẹbọ wọn si jẹ́ ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun ti fadakà; ìtẹbọ mejimeji li o wà nisalẹ apáko kọkan.
31. O si ṣe ọpá igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na,
32. Ati ọpá marun fun apáko ìha keji agọ́ na, ati ọpá marun fun apáko agọ́ na fun ìha ìwọ-õrùn.
33. O si ṣe ọpá ãrin o yọ jade lara apáko wọnni, lati opin ekini dé ekeji.
34. O si fi wurà bò apáko wọnni, o si fi wurà ṣe oruka wọn, lati ṣe ipò fun ọpá wọnni, o si fi wurà bò ọpá wọnni.