Eks 33:4-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nigbati awọn enia na si gbọ́ ihin buburu yi, nwọn kãnu: enia kan kò si wọ̀ ohun ọṣọ́ rẹ̀.

5. OLUWA si ti wi fun Mose pe, Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, ọlọ́rùn lile ni nyin: bi emi ba gòke wá sãrin rẹ ni iṣẹju kan, emi o si run ọ: njẹ nisisiyi bọ́ ohun ọṣọ́ rẹ kuro lara rẹ, ki emi ki o le mọ̀ ohun ti emi o fi ọ ṣe.

6. Awọn ọmọ Israeli si bọ́ ohun ọṣọ́ wọn kuro lara wọn leti oke Horebu.

7. Mose si mú agọ́ na, o si pa a lẹhin ibudó, li òkere rére si ibudó; o pè e ni Agọ́ ajọ. O si ṣe, olukuluku ẹniti mbère OLUWA o jade lọ si agọ́ ajọ, ti o wà lẹhin ibudó.

8. O si ṣe, nigbati Mose jade lọ si ibi agọ́ na, gbogbo awọn enia a si dide duro, olukuluku a si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀, a ma wò ẹhin Mose, titi yio fi dé ibi agọ́ na.

9. O si ṣe, bi Mose ti dé ibi agọ́ na, ọwọ̀n awọsanma sọkalẹ, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: OLUWA si bá Mose sọ̀rọ.

Eks 33