12. Nigbati iwọ ba kà iye awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi ẹgbẹ wọn, nigbana li olukuluku ọkunrin yio mú irapada ọkàn rẹ̀ fun OLUWA wá, nigbati iwọ ba kà iye wọn; ki ajakalẹ-àrun ki o máṣe si ninu wọn, nigbati iwọ ba nkà iye wọn.
13. Eyi ni nwọn o múwa, olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, àbọ ṣekeli, ani ṣekeli ibi mimọ́: (ogún gera ni ṣekeli kan:) àbọ ṣekeli li ọrẹ fun OLUWA.
14. Olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, ni yio fi ọrẹ fun OLUWA.
15. Olowo ki o san jù bẹ̃ lọ, bẹ̃li awọn talaka kò si gbọdọ di li àbọ ṣekeli, nigbati nwọn ba mú ọrẹ wá fun OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin.
16. Iwọ o si gbà owo ètutu na lọwọ awọn ọmọ Israeli, iwọ o si fi i lelẹ fun ìsin agọ́ ajọ; ki o le ma ṣe iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin.
17. OLUWA si sọ fun Mose pe,
18. Iwọ o si ṣe agbada idẹ kan, ati ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fun wiwẹ̀: iwọ o si gbẹ́ e kà agbedemeji agọ́ ajọ, ati pẹpẹ nì, iwọ o si pọn omi sinu rẹ̀.
19. Nitori Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn nibẹ̀:
20. Nigbati nwọn ba nwọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, nwọn o fi omi wẹ̀ ki nwọn ki o má ba kú: tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ nì lati ṣe ìsin, lati ru ẹbọ sisun ti a fi iná ṣe si OLUWA:
21. Nwọn o si wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn, ki nwọn ki o má ba kú: yio si di ìlana fun wọn lailai, fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lati irandiran wọn.