Nwọn o si ṣe apoti igi ṣittimu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀.