Eks 21:23-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Bi ibi kan ba si pẹlu, njẹ ki iwọ ki o fi ẹmi dipò ẹmi.

24. Fi oju dipò oju, ehín dipò ehín, ọwọ́ dipò ọwọ́, ẹsẹ̀ dipò ẹsẹ̀.

25. Fi ijóna dipò ijóna, ọgbẹ́, dipò ọgbẹ́, ìna dipò ìna.

26. Bi o ba ṣepe ẹnikan ba lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi ẹrú rẹ̀ obinrin li oju ti o si fọ́; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori oju rẹ̀.

27. Bi o ba si ká ehín ẹrú rẹ̀ ọkunrin, tabi ehín ẹrú rẹ̀ obinrin; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori ehín rẹ̀.

28. Bi akọmalu ba kàn ọkunrin tabi obinrin ti o si kú: sísọ ni ki a sọ akọmalu na li okuta pa bi o ti wù ki o ṣe, ki a má si ṣe jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn ọrùn oni-akọmalu na yio mọ́.

29. Ṣugbọn bi o ba ṣepe akọmalu na a ti ma fi iwo rẹ̀ kàn nigba atijọ, ti a si ti kìlọ fun oluwa rẹ̀, ti kò si sé e mọ, ṣugbọn ti o pa ọkunrin tabi obinrin, akọmalu na li a o sọ li okuta pa, oluwa rẹ̀ li a o si lù pa pẹlu.

30. Bi o ba si ṣepe a bù iye owo kan fun u, njẹ iyekiye ti a bù fun u ni yio fi ṣe irapada ẹmi rẹ̀.

31. Iba kàn ọmọkunrin, tabi iba kàn ọmọbinrin, gẹgẹ bi irú idajọ yi li a o ṣe si i.

Eks 21