Eks 19:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Mose si sọkalẹ lati ori oke na wá sọdọ awọn enia, o si yà awọn enia si mimọ́, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn.

15. O si wi fun awọn enia pe, Ẹ mura dè ijọ́ kẹta: ki ẹ máṣe sunmọ aya nyin.

16. O si ṣe, li owurọ̀ ijọ́ kẹta, ni ãrá ati mànamána wà, ati awọsanma ṣíṣu dùdu lori òke na, ati ohùn ipè na si ndún kikankikan; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti o wà ni ibudó warìri.

17. Mose si mú awọn enia jade lati ibudó wá lati bá Ọlọrun pade; nwọn si duro ni ìha isalẹ oke na.

18. Oke Sinai si jẹ́ kìki ẽfi, nitoriti OLUWA sọkalẹ sori rẹ̀ ninu iná: ẽfi na si goke bi ẽfi ileru, gbogbo oke na si mì tìtì.

19. O si ṣe ti ohùn ipè si dún, ti o si mulẹ kijikiji, Mose sọ̀rọ, Ọlọrun si fi ãrá da a li ohùn.

20. OLUWA si sọkalẹ wá si oke Sinai, lori oke na: OLUWA si pè Mose lori oke na; Mose si goke lọ.

21. OLUWA si wi fun Mose pe, Sọkalẹ, kìlọ fun awọn enia, ki nwọn ki o má ba yà sọdọ OLUWA lati bẹ̀ ẹ wò, ki ọ̀pọ ki o má ba ṣegbe ninu wọn.

22. Si jẹ ki awọn alufa pẹlu, ti o sunmọ OLUWA, ki o yà ara wọn si mimọ́, ki OLUWA ki o má ba kọlù wọn.

Eks 19