4. Mose si kepè OLUWA, wipe, Kili emi o ṣe fun awọn enia yi? nwọn fẹrẹ̀ sọ mi li okuta.
5. OLUWA si wi fun Mose pe, Kọja lọ siwaju awọn enia na, ki o si mú ninu awọn àgbagba Israeli pẹlu rẹ, ki o si mú ọpá rẹ, ti o fi lù odò nì li ọwọ́ rẹ, ki o si ma lọ.
6. Kiyesi i, emi o duro niwaju rẹ nibẹ̀ lori okuta ni Horebu; iwọ o si lù okuta na, omi yio si jade ninu rẹ̀, ki awọn enia ki o le mu. Mose si ṣe bẹ̃ li oju awọn àgbagba Israeli.
7. O si sọ orukọ ibẹ̀ ni Massa, ati Meriba, nitori asọ̀ awọn ọmọ Israeli, ati nitoriti nwọn dan OLUWA wò pe, OLUWA ha mbẹ lãrin wa, tabi kò si?