O si wá si agbedemeji ogun awọn ara Egipti ati ogun Israeli; o si ṣe awọsanma ati òkunkun fun awọn ti ọhún, ṣugbọn o ṣe imọlẹ li oru fun awọn ti ihin: bẹ̃li ekini kò sunmọ ekeji ni gbogbo oru na.