14. Nitoriti OLUWA yio jà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pa ẹnu nyin mọ́.
15. OLUWA si wi fun Mose pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkepè mi? sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o tẹ̀ siwaju:
16. Ṣugbọn iwọ gbé ọpá rẹ soke, ki iwọ ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju okun ki o si yà a meji: awọn ọmọ Israeli yio si là ãrin okun na kọja ni iyangbẹ ilẹ.
17. Ati emi kiyesi i, emi o mu àiya awọn ara Egipti le, nwọn o si tẹle wọn: a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori gbogbo ogun rẹ̀, ati lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀.
18. Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba gbà ogo lori Farao, lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀.