1. OLUWA si wi fun Mose pe,
2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o dari, ki nwọn ki o si dó si iwaju Pi-hahirotu, li agbedemeji Migdolu on okun, niwaju Baal-sefoni: lọkankan rẹ̀ li ẹba okun ni ki ẹnyin ki o dó si.
3. Nitoriti Farao yio wi niti awọn ọmọ Israeli pe, Nwọn há ni ilẹ na, ijù na sé wọn mọ́.
4. Emi o si mu àiya Farao le, ti yio fi lepa wọn; a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori ogun rẹ̀ gbogbo; ki awọn ara Egipti ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA. Nwọn si ṣe bẹ̃.
5. A si wi fun ọba Egipti pe, awọn enia na sá: àiya Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀ si yi si awọn enia na, nwọn si wipe, Ẽṣe ti awa fi ṣe eyi, ti awa fi jẹ ki Israeli ki o lọ kuro ninu ìsin wa?
6. O si dì kẹkẹ́ rẹ̀, o si mú awọn enia rẹ̀ pẹlu rẹ̀.
7. O si mú ẹgbẹta ãyo kẹkẹ́, ati gbogbo kẹkẹ́ Egipti, ati olori si olukuluku wọn.
8. OLUWA si mu àiya Farao ọba Egipti le, o si lepa awọn ọmọ Israeli: ọwọ́ giga li awọn ọmọ Israeli si fi jade lọ.
9. Ṣugbọn awọn ara Egipti lepa wọn, gbogbo ẹṣin ati kẹkẹ́ Farao, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, ati awọn ogun rẹ̀, o si lé wọn bá, nwọn duro li ẹba okun ni ìha Pi-hahirotu niwaju Baal-sefoni.
10. Nigbati Farao si nsunmọtosi, awọn ọmọ Israeli gbé oju soke, si kiyesi i, awọn ara Egipti mbọ̀ lẹhin wọn; ẹ̀ru si bà wọn gidigidi: awọn ọmọ Israeli si kigbe pè OLUWA.