Nwọn si yan àkara iyẹfun pipò alaiwu ti nwọn mú jade ti Egipti wá, nwọn kò sa fi iwukàra si i; nitoriti a tì wọn jade kuro ni Egipti, nwọn kò si le duro, bẹ̃ni nwọn kò pèse ohun jijẹ kan fun ara wọn.