Ẹk. Jer 5:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. RANTI, Oluwa, ohun ti o de sori wa; rò ki o si wò ẹ̀gan wa!

2. A fi ogún wa le awọn alejo lọwọ, ile wa fun awọn ajeji.

3. Awa jẹ alaini obi, baba kò si, awọn iyá wa dabi opó.

4. Awa ti fi owo mu omi wa; a nta igi wa fun wa.

5. Awọn ti nlepa wa sunmọ ọrùn wa: ãrẹ̀ mu wa, awa kò si ni isimi.

Ẹk. Jer 5