14. Nwọn ti rin kiri bi afọju ni ita, nwọn di alaimọ́ fun ẹ̀jẹ tobẹ̃ ti enia kò le fi ọwọ kan aṣọ wọn.
15. Nwọn nkigbe si wọn pe, ẹ lọ! alaimọ́ ni! ẹ lọ! ẹ lọ! ẹ máṣe fi ọwọ kan a! nigbati nwọn salọ, nwọn si rìn kiri pẹlu: nwọn nwi lãrin awọn orilẹ-ède pe, awọn kì o ṣatipo nibẹ mọ.
16. Oju Oluwa ti tú wọn ka: on kì o fiyesi wọn mọ: nwọn kò buyin fun awọn alufa, nwọn kò ṣãnu fun awọn àgbagba.
17. Bi o ṣe ti wa ni, oju wa nwọ̀na siwaju ati siwaju, fun iranlọwọ wa ti o jẹ asan: lori ile-iṣọ wa, awa nwọ̀na fun orilẹ-ède, ti kò le ràn ni lọwọ.
18. Nwọn dẹkun si ipa ọ̀na wa, ti awa kò le rìn ita wa: opin wa sunmọ tosi, ọjọ wa pé; nitori opin wa de.