Ẹk. Jer 3:57-66 Yorùbá Bibeli (YCE)

57. Iwọ sunmọ itosi li ọjọ ti emi kigbe pè ọ: iwọ wipe: Má bẹ̀ru!

58. Oluwa, iwọ ti gba ijà mi jà; iwọ ti rà ẹmi mi pada.

59. Oluwa, iwọ ti ri inilara mi, ṣe idajọ ọran mi!

60. Iwọ ti ri gbogbo igbẹsan wọn, gbogbo èro buburu wọn si mi.

61. Iwọ ti gbọ́ ẹ̀gan wọn, Oluwa, gbogbo èro buburu wọn si mi.

62. Ète awọn wọnni ti o dide si mi, ati ipinnu wọn si mi ni gbogbo ọjọ.

63. Kiyesi ijoko wọn ati idide wọn! emi ni orin-ẹsin wọn.

64. San ẹsan fun wọn, Oluwa, gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn!

65. Fun wọn ni ifọju ọkàn, ègun rẹ lori wọn!

66. Fi ibinu lepa wọn, ki o si pa wọn run kuro labẹ ọrun Oluwa!

Ẹk. Jer 3