Ẹk. Jer 3:24-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀.

25. Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀.

26. O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa.

27. O dara fun ọkunrin, ki o gbe àjaga ni igba-ewe rẹ̀.

28. Ki o joko on nikan, ki o si dakẹ, nitori Ọlọrun ti gbe e le ori rẹ̀.

29. Ki o fi ẹnu rẹ̀ sinu ẽkuru; pe bọya ireti le wà:

30. Ki o fi ẹ̀rẹkẹ fun ẹniti o lù u; ki o kún fun ẹ̀gan patapata.

31. Nitoriti Oluwa kì yio ṣá ni tì lailai:

32. Bi o tilẹ mu ibanujẹ wá, sibẹ on o ni irọnu gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀.

33. Nitori on kì ifẹ ipọn-ni-loju lati ọkàn rẹ̀ wá, bẹ̃ni kì ibà ọmọ enia ninu jẹ.

34. Lati tẹ̀ gbogbo ara-tubu ilẹ-aiye mọlẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀.

Ẹk. Jer 3