10. On jẹ bi ẹranko beari ti o ba dè mi, bi kiniun ni ibi ìkọkọ.
11. O ti mu mi ṣina li ọ̀na mi, o si fà mi ya pẹrẹpẹrẹ: o ti sọ mi di ahoro.
12. O ti fà ọrun rẹ̀, o si fi mi ṣe itasi fun ọfa rẹ̀.
13. O ti mu ki ọfà apó rẹ̀ wọ inu-ẹdọ mi lọ.
14. Emi jẹ ẹni ẹsin fun gbogbo enia mi; orin wọn ni gbogbo ọjọ.
15. O ti fi ìkoro mu mi yo, o ti mu mi mu omi wahala.
16. O ti fi ọta ṣẹ́ ehín mi, o tẹ̀ mi mọlẹ ninu ẽru.
17. Iwọ si ti mu ọkàn mi jina réré si alafia; emi gbagbe rere.
18. Emi si wipe, Agbara mi ati ireti mi ṣègbe kuro lọdọ Oluwa.
19. Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro.
20. Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi.