Efe 4:28-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini.

29. Ẹ máṣe jẹ ki ọ̀rọ idibajẹ kan ti ẹnu nyin jade, ṣugbọn iru eyiti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o le mã fi ore-ọfẹ fun awọn ti ngbọ́.

30. Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande.

31. Gbogbo ìwa kikorò, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọ̀rọ buburu ni ki a mu kuro lọdọ nyin, pẹlu gbogbo arankàn:

32. Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.

Efe 4