Deu 9:9-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nigbati mo gòke lọ sori òke lati gbà walã okuta wọnni, ani walã majẹmu nì ti OLUWA bá nyin dá, nigbana mo gbé ogoji ọsán, ati ogoji oru lori òke na, emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃li emi kò mu omi.

10. OLUWA si fi walã okuta meji fun mi, ti a fi ika Ọlọrun kọ; ati lara wọn li a kọ ọ gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ na, ti OLUWA bá nyin sọ li òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì.

11. O si ṣe li opin ogoji ọsán ati ogoji oru, ti OLUWA fi walã okuta meji nì fun mi, ani walã majẹmu nì.

12. OLUWA si wi fun mi pe, Dide, sọkalẹ kánkán lati ihin lọ; nitoriti awọn enia rẹ, ti iwọ mú lati ilẹ Egipti jade wá, ti bà ara wọn jẹ́; nwọn yipada kánkán kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun wọn; nwọn ti yá ere didà fun ara wọn.

13. OLUWA sọ fun mi pẹlu pe, Emi ti ri enia yi, si kiyesi i, enia ọlọrùn lile ni:

14. Yàgo fun mi, ki emi ki o pa wọn run, ki emi si pa orukọ wọn rẹ́ kuro labẹ ọrun: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède ti o lagbara ti o si pọ̀ jù wọn lọ.

15. Emi si pada, mo si sọkalẹ lati ori òke nì wá, òke na si njóna: walã meji ti majẹmu nì si wà li ọwọ́ mi mejeji.

16. Mo si wò, si kiyesi i, ẹnyin ti ṣẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin si ti yá ẹgbọrọ-malu didà fun ara nyin: ẹnyin ti yipada kánkán kuro li ọ̀na ti OLUWA ti palaṣẹ fun nyin.

17. Emi si mú walã meji nì, mo si sọ wọn silẹ kuro li ọwọ́ mi mejeji, mo si fọ́ wọn niwaju nyin.

18. Emi si wolẹ niwaju OLUWA bi ti iṣaju, li ogoji ọsán ati ogoji oru; emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni emi kò mu omi; nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin ti ẹnyin ṣẹ̀, ni ṣiṣe buburu li oju OLUWA, lati mu u binu.

19. Nitoriti emi bẹ̀ru ibinu ati irunu OLUWA si nyin lati pa nyin run. OLUWA si gbọ́ ti emi nigbana pẹlu.

20. OLUWA si binu si Aaroni gidigidi ti iba fi pa a run: emi si gbadura fun Aaroni nigbana pẹlu.

21. Emi si mú ẹ̀ṣẹ nyin, ẹgbọrọ-malu ti ẹnyin ṣe, mo si fi iná sun u, mo si gún u, mo si lọ̀ ọ kúnna, titi o fi dabi ekuru: mo si kó ekuru rẹ̀ lọ idà sinu odò ti o ti òke na ṣànwalẹ.

22. Ati ni Tabera, ati ni Massa, ati ni Kibrotu-hattaafa, ẹnyin mu OLUWA binu.

23. Nigbati OLUWA rán nyin lati Kadeṣi-barnea lọ, wipe, Gòke lọ ki o si gbà ilẹ na ti mo fi fun nyin; nigbana li ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin kò si gbà a gbọ́, bẹ̃li ẹnyin kò si fetisi ohùn rẹ̀.

24. Ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA lati ọjọ́ ti mo ti mọ̀ nyin.

25. Mo si wolẹ niwaju OLUWA li ogoji ọsán ati li ogoji oru, bi mo ti wolẹ niṣaju; nitoriti OLUWA wipe, on o run nyin.

26. Mo si gbadura sọdọ OLUWA wipe, Oluwa ỌLỌRUN, máṣe run awọn enia rẹ ati iní rẹ, ti iwọ ti fi titobi rẹ̀ ràsilẹ, ti iwọ mú lati Egipti jade wá pẹlu ọwọ́ agbara.

27. Ranti Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu awọn iranṣẹ rẹ; máṣe wò agídi awọn enia yi, tabi ìwabuburu wọn, tabi ẹ̀ṣẹ wọn:

28. Ki awọn enia ilẹ na ninu eyiti iwọ ti mú wa jade wá ki o má ba wipe, Nitoriti OLUWA kò le mú wọn dé ilẹ na ti o ti ṣe ileri fun wọn, ati nitoriti o korira wọn, li o ṣe mú wọn jade wá lati pa wọn li aginjù.

Deu 9