1. GBOGBO ofin ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati ṣe, ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹnyin si ma pọ̀ si i, ki ẹnyin si wọnu rẹ̀ lọ lati gbà ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin.
2. Ki iwọ ki o si ranti ọ̀na gbogbo ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti mu ọ rìn li aginjù lati ogoji ọdún yi wá, lati rẹ̀ ọ silẹ, ati lati dan ọ wò, lati mọ̀ ohun ti o wà li àiya rẹ, bi iwọ o pa ofin rẹ̀ mọ́, bi bẹ̃kọ.