8. Ṣugbọn nitoriti OLUWA fẹ́ nyin, ati nitoriti on fẹ́ pa ara ti o ti bú fun awọn baba nyin mọ́, ni OLUWA ṣe fi ọwọ́ agbara mú nyin jade, o si rà nyin pada kuro li oko-ẹrú, kuro li ọwọ́ Farao ọba Egipti.
9. Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ, on li Ọlọrun; Ọlọrun olõtọ, ti npa majẹmu mọ́ ati ãnu fun awọn ti o fẹ́ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ́ dé ẹgbẹrun iran;
10. Ti o si nsan a pada fun awọn ti o korira rẹ̀ li oju wọn, lati run wọn: on ki yio jafara fun ẹniti o korira rẹ̀, on o san a fun u loju rẹ̀.
11. Nitorina ki iwọ ki o pa ofin, ati ìlana, ati idajọ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe wọn.
12. Yio si ṣe, nitoriti ẹnyin fetisi idajọ wọnyi, ti ẹ si npa wọn mọ́, ti ẹ si nṣe wọn, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio ma pa majẹmu ati ãnu mọ́ fun ọ, ti o ti bura fun awọn baba rẹ: