8. Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworán apẹrẹ kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti mbẹ ni ilẹ nisalẹ, tabi ti mbẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ:
9. Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitoripe emi OLUWA Ọlọrun rẹ Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, ati lara iran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi.
10. Emi a si ma ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si pa ofin mi mọ́.
11. Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ li asan: nitoriti OLUWA ki yio mu ẹniti o pè orukọ rẹ̀ li asan bi alailẹṣẹ lọrùn.
12. Kiyesi ọjọ́-isimi lati yà a simimọ́, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ.
13. Ijọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo:
14. Ṣugbọn ọjọ́ keje li ọjọ́-isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ, ati ohunọ̀sin rẹ kan, ati alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ; ki ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ki o le simi gẹgẹ bi iwọ.
15. Si ranti pe iwọ ti ṣe iranṣẹ ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ibẹ̀ jade wá nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa: nitorina li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe paṣẹ fun ọ lati pa ọjọ́-isimi mọ́.
16. Bọ̀wọ fun baba ati iya rẹ, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ, ati ki o le dara fun ọ, ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
17. Iwọ kò gbọdọ pania.
18. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga.