Deu 5:27-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Iwọ sunmọtosi, ki o si gbọ́ gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa yio wi: ki iwọ ki o sọ fun wa gbogbo ohun ti OLUWA Ọlọrun wa yio sọ fun ọ: awa o si gbọ́, awa o si ṣe e.

28. OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, nigbati ẹnyin sọ fun mi; OLUWA si sọ fun mi pe, emi ti gbọ́ ohùn ọ̀rọ awọn enia yi, ti nwọn sọ fun ọ: nwọn wi rere ni gbogbo eyiti nwọn sọ.

29. Irú ọkàn bayi iba ma wà ninu wọn, ki nwọn ki o le ma bẹ̀ru mi, ki nwọn ki o si le ma pa gbogbo ofin mi mọ́ nigbagbogbo, ki o le dara fun wọn, ati fun awọn ọmọ wọn titilai!

30. Lọ wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ sinu agọ́ nyin.

31. Ṣugbọn, iwọ, duro nihin lọdọ mi, emi o si sọ ofin nì gbogbo fun ọ, ati ìlana, ati idajọ, ti iwọ o ma kọ́ wọn, ki nwọn ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ na ti mo ti fi fun wọn lati ní.

32. Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesi ati ṣe bi OLUWA Ọlọrun nyin ti paṣẹ fun nyin: ki ẹnyin ki o máṣe yi si ọtún tabi si òsi.

33. Ki ẹnyin ki o si ma rìn ninu gbogbo ọ̀na ti OLUWA Ọlọrun nyin palaṣẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le yè, ki o si le dara fun nyin, ati ki ẹnyin ki o le mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ ti ẹnyin yio ní.

Deu 5