1. MOSE si pè gbogbo Israeli, o si wi fun wọn pe, Israeli, gbọ́ ìlana ati idajọ ti emi nsọ li etí nyin li oni, ki ẹnyin ki o le kọ́ wọn, ki ẹ si ma pa wọn mọ́, lati ma ṣe wọn.
2. OLUWA Ọlọrun wa bá wa dá majẹmu ni Horebu.
3. OLUWA kò bá awọn baba wa dá majẹmu yi, bikoṣe awa, ani awa, ti gbogbo wa mbẹ lãye nihin li oni.
4. OLUWA bá nyin sọ̀rọ li ojukoju lori òke na, lati ãrin iná wá,
5. (Emi duro li agbedemeji OLUWA ati ẹnyin ni ìgba na, lati sọ ọ̀rọ OLUWA fun nyin: nitoripe ẹnyin bẹ̀ru nitori iná na, ẹnyin kò si gòke lọ sori òke na;) wipe,
6. Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wá.
7. Iwọ kò gbọdọ ní ọlọrun miran pẹlu mi.