41. Nigbana ni Mose yà ilu mẹta sọ̀tọ ni ìha ẹ̀bá Jordani si ìha ìla-õrùn.
42. Ki apania ki o le ma sá sibẹ̀, ti o ba ṣì ẹnikeji rẹ̀ pa, ti kò si korira rẹ̀ ni ìgba atijọ rí; ati pe bi o ba sá si ọkan ninu ilu wọnyi ki o le là:
43. Beseri ni ijù, ni ilẹ pẹtẹlẹ̀, ti awọn ọmọ Reubeni; ati Ramotu ni Gileadi, ti awọn ọmọ Gadi; ati Golani ni Baṣani, ti awọn ọmọ Manasse.
44. Eyi li ofin na ti Mose filelẹ niwaju awọn ọmọ Israeli:
45. Wọnyi li ẹrí, ati ìlana, ati idajọ, ti Mose filelẹ fun awọn ọmọ Israeli, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá;
46. Ni ìha ẹ̀bá Jordani, ni afonifoji ti o kọjusi Beti-peori, ni ilẹ Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni, ẹniti Mose ati awọn ọmọ Israeli kọlù, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá:
47. Nwọn si gbà ilẹ rẹ̀, ati ilẹ Ogu ọba Baṣani, awọn ọba Amori mejeji ti mbẹ ni ìha ẹ̀bá Jordani si ìha ìla-õrùn;
48. Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ani dé òke Sioni (ti iṣe Hermoni,)
49. Ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ nì, ni ìha ẹ̀bá Jordani ni ìha ìla-õrùn, ani dé okun pẹtẹlẹ̀ nì, nisalẹ awọn orisun Pisga.