Deu 4:39-45 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ li oni, ki o si rò li ọkàn rẹ pe, OLUWA on li Ọlọrun loke ọrun, ati lori ilẹ nisalẹ: kò sí ẹlomiran.

40. Nitorina ki iwọ ki o pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati ofin rẹ̀, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o le dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ lori ilẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lailai.

41. Nigbana ni Mose yà ilu mẹta sọ̀tọ ni ìha ẹ̀bá Jordani si ìha ìla-õrùn.

42. Ki apania ki o le ma sá sibẹ̀, ti o ba ṣì ẹnikeji rẹ̀ pa, ti kò si korira rẹ̀ ni ìgba atijọ rí; ati pe bi o ba sá si ọkan ninu ilu wọnyi ki o le là:

43. Beseri ni ijù, ni ilẹ pẹtẹlẹ̀, ti awọn ọmọ Reubeni; ati Ramotu ni Gileadi, ti awọn ọmọ Gadi; ati Golani ni Baṣani, ti awọn ọmọ Manasse.

44. Eyi li ofin na ti Mose filelẹ niwaju awọn ọmọ Israeli:

45. Wọnyi li ẹrí, ati ìlana, ati idajọ, ti Mose filelẹ fun awọn ọmọ Israeli, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá;

Deu 4