Deu 4:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ nisisiyi Israeli, fetisi ìlana ati idajọ, ti emi nkọ́ nyin, lati ṣe wọn; ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹ si lọ igba ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin fi fun nyin.

2. Ẹ kò gbọdọ fikún ọ̀rọ na ti mo palaṣẹ fun nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bù kuro ninu rẹ̀, ki ẹnyin ki o le pa ofin OLUWA Ọlọrun nyin mọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin.

3. Oju nyin ti ri ohun ti OLUWA ṣe nitori Baali-peori: nitoripe gbogbo awọn ọkunrin ti o tẹlé Baali-peori lẹhin, OLUWA Ọlọrun rẹ ti run wọn kuro lãrin rẹ.

4. Ṣugbọn ẹnyin ti o faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gbogbo nyin mbẹ lãye li oni.

Deu 4