Deu 34:5-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Bẹ̃ni Mose iranṣẹ OLUWA kú nibẹ̀ ni ilẹ Moabu, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA.

6. O si sin i ninu afonifoji ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Beti-peori; ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o mọ̀ iboji rẹ̀ titi di oni-oloni.

7. Mose si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún nigbati o kú: oju rẹ̀ kò ṣe baìbai, bẹ̃li agbara rẹ̀ kò dinku.

8. Awọn ọmọ Israeli si sọkun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu li ọgbọ̀n ọjọ́: bẹ̃li ọjọ́ ẹkún ati ọ̀fọ Mose pari.

Deu 34