28. Nitori orilẹ-ède ti kò ní ìmọ ni nwọn, bẹ̃ni kò sí òye ninu wọn.
29. Ibaṣepe nwọn gbọ́n, ki òye eyi ki o yé wọn, nwọn iba rò igbẹhin wọn!
30. Ẹnikan iba ti ṣe lé ẹgbẹrun, ti ẹni meji iba si lé ẹgbãrun sá, bikoṣepe bi Apata wọn ti tà wọn, ti OLUWA si fi wọn tọrẹ?
31. Nitoripe apata wọn kò dabi Apata wa, ani awọn ọtá wa tikalawọn ni nṣe onidajọ.
32. Nitoripe igi-àjara wọn, ti igi-àjara Sodomu ni, ati ti igbẹ́ Gomorra: eso-àjara wọn li eso-àjara orõro, ìdi wọn korò:
33. Ọti-waini wọn iwọ ti dragoni ni, ati oró mimu ti pamọlẹ̀.
34. Eyi ki a tojọ sọdọ mi ni ile iṣura, ti a si fi èdidi dì ninu iṣura mi?
35. Ti emi ni igbẹsan, ati ẹsan, li akokò ti ẹsẹ̀ wọn yio yọ́: nitoriti ọjọ́ idamu wọn sunmọtosi, ohun ti o si mbọ̀ wa bá wọn nyára wá.
36. Nitoripe OLUWA yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si kãnu awọn iranṣẹ rẹ̀; nigbati o ba ri pe agbara wọn lọ tán, ti kò si sí ẹnikan ti a sé mọ́, tabi ti o kù.
37. On o si wipe, Nibo li oriṣa wọn gbé wà, apata ti nwọn gbẹkẹle: