1. FETISILẸ, ẹnyin ọrun, emi o si sọ̀rọ; si gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi, iwọ aiye:
2. Ẹkọ́ mi yio ma kán bi ojò ohùn mi yio ma sẹ̀ bi ìri; bi òjo winiwini sara eweko titun, ati bi ọ̀wara òjo sara ewebẹ̀:
3. Nitoriti emi o kokikí orukọ OLUWA kiri: ẹ fi ọlá fun Ọlọrun wa.
4. Apata na, pipé ni iṣẹ rẹ̀; nitoripe idajọ ni gbogbo ọ̀na rẹ̀: Ọlọrun otitọ ati alàiṣegbe, ododo ati otitọ li on.
5. Nwọn ti bà ara wọn jẹ́ lọdọ rẹ̀, nwọn ki iṣe ọmọ rẹ̀, àbuku wọn ni; iran arekereke ati wiwọ́ ni nwọn.
6. Bayi li ẹnyin o ha san ẹsan fun OLUWA, ẹnyin aṣiwere enia ati alaigbọn? On ha kọ́ ni baba rẹ ti o rà ọ? on li o dá ọ, on li o si fi ẹsẹ̀ rẹ mulẹ?
7. Ranti ọjọ́ igbãni, ronu ọdún iraniran: bi baba rẹ lere yio si fihàn ọ; bi awọn àgba rẹ, nwọn o si sọ fun ọ.
8. Nigbati Ọga-ogo pín iní fun awọn orilẹ-ède, nigbati o tu awọn ọmọ enia ká, o pàla awọn enia na gẹgẹ bi iye awọn ọmọ Israeli.
9. Nitoripe ipín ti OLUWA li awọn enia rẹ̀; Jakobu ni ipín iní rẹ̀.
10. O ri i ni ilẹ aṣalẹ̀, ati ni aginjù nibiti ẹranko nke; o yi i ká, o tọju rẹ̀, o pa a mọ́ bi ẹyin oju rẹ̀:
11. Bi idì ti irú itẹ́ rẹ̀, ti iràbaba sori ọmọ rẹ̀, ti inà iyẹ́-apa rẹ̀, ti igbé wọn, ti ima gbé wọn lọ lori iyẹ́-apa rẹ̀:
12. Bẹ̃ni OLUWA nikan ṣamọ̀na rẹ̀, kò si sí oriṣa pẹlu rẹ̀.
13. O mu u gùn ibi giga aiye, ki o le ma jẹ eso oko; o si jẹ ki o mu oyin lati inu apata wá, ati oróro lati inu okuta akọ wá;
14. Ori-amọ́ malu, ati warà agutan, pẹlu ọrá ọdọ-agutan, ati àgbo irú ti Baṣani, ati ewurẹ, ti on ti ọrá iwe alikama; iwọ si mu ẹ̀jẹ eso-àjara, ani ọti-waini.
15. Ṣugbọn Jeṣuruni sanra tán, o si tapa: iwọ sanra tán, iwọ kì tan, ọrá bò ọ tán: nigbana li o kọ̀ Ọlọrun ti o dá a, o si gàn Apata ìgbala rẹ̀.
16. Nwọn fi oriṣa mu u jowú, ohun irira ni nwọn fi mu u binu.
17. Nwọn rubọ si iwin-buburu ti ki iṣe Ọlọrun, si oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, si oriṣa ti o hù ni titun, ti awọn baba nyin kò bẹ̀ru.