Deu 31:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Mose si pè Joṣua, o si wi fun u li oju gbogbo Israeli pe, Ṣe giri ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio bá awọn enia yi lọ si ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba wọn, lati fi fun wọn; iwọ o si mu wọn gbà a.

8. Ati OLUWA on li o nlọ ṣaju rẹ; on ni yio pẹlu rẹ, on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ: máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ.

9. Mose si kọwe ofin yi, o si fi i fun awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti ima rù apoti majẹmu OLUWA, ati fun gbogbo awọn àgba Israeli.

10. Mose si paṣẹ fun wọn, wipe, Li opin ọdún meje meje li akokò ọdún idasilẹ, ni ajọ agọ́.

11. Nigbati gbogbo Israeli ba wá farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti on o gbé yàn, ki iwọ ki o kà ofin yi niwaju gbogbo Israeli li etí wọn.

12. Kó awọn enia na jọ, awọn ọkunrin ati awọn obinrin ati awọn ọmọde, ati alejò rẹ ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki nwọn ki o le gbọ́, ati ki nwọn ki o le kọ ati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ati ki nwọn ki o ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi;

13. Ati ki awọn ọmọ wọn, ti kò mọ̀, ki o le gbọ́, ki nwọn si kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngóke Jordani lọ lati gbà a.

14. OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, ọjọ́ rẹ sunmọ-etile ti iwọ o kú: pè Joṣua, ki ẹ si fara nyin hàn ninu agọ́ ajọ, ki emi ki o le fi aṣẹ lé e lọwọ. Mose ati Joṣua si lọ, nwọn si fara wọn hàn ninu agọ́ ajọ.

15. OLUWA si yọ si wọn ninu agọ́ na ninu ọwọ̀n awọsanma: ọwọ̀n awọsanma na si duro loke ẹnu-ọ̀na agọ́ na.

16. OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, iwọ o sùn pẹlu awọn baba rẹ; awọn enia yi yio si dide, nwọn o si ma ṣe àgbere tọ̀ awọn oriṣa ilẹ na lẹhin, nibiti nwọn nlọ lati gbé inu wọn, nwọn o si kọ̀ mi silẹ, nwọn o si dà majẹmu mi ti mo bá wọn dá.

17. Nigbana ni ibinu mi yio rú si wọn li ọjọ́ na, emi o si kọ̀ wọn silẹ, emi o si pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, a o si jẹ wọn run, ati ibi pupọ̀ ati iyọnu ni yio bá wọn; tobẹ̃ ti nwọn o si wi li ọjọ́ na pe, Kò ha jẹ́ pe nitoriti Ọlọrun wa kò sí lãrin wa ni ibi wọnyi ṣe bá wa?

18. Emi o fi oju mi pamọ́ patapata li ọjọ́ na, nitori gbogbo ìwabuburu ti nwọn o ti hù, nitori nwọn yipada si oriṣa.

Deu 31