Deu 31:24-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. O si ṣe, nigbati Mose pari kikọ ọ̀rọ ofin yi tán sinu iwé, titi nwọn fi pari,

25. Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ti nrù apoti majẹmu OLUWA, wipe,

26. Gbà iwé ofin yi, ki o si fi i sapakan apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o ma wà nibẹ̀ fun ẹrí si ọ.

27. Nitoripe mo mọ̀ ọ̀tẹ rẹ, ati lile ọrùn rẹ: kiyesi i, nigbati emi wà lãye sibẹ̀ pẹlu nyin li oni, ọlọtẹ̀ li ẹnyin ti nṣe si OLUWA; melomelo si ni lẹhin ikú mi?

28. Pè gbogbo awọn àgba ẹ̀ya nyin jọ sọdọ mi, ati awọn ijoye nyin, ki emi ki o le sọ ọ̀rọ wọnyi li etí wọn ki emi ki o si pè ọrun ati aiye jẹri tì wọn.

29. Nitori mo mọ̀ pe lẹhin ikú mi ẹnyin o bà ara nyin jẹ́ patapata, ati pe ẹnyin o yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin; ibi yio si bá nyin li ọjọ́ ikẹhin; nitoriti ẹnyin o ma ṣe buburu li oju OLUWA, lati fi iṣẹ ọwọ́ nyin mu u binu.

30. Mose si sọ ọ̀rọ orin yi li etí gbogbo ijọ Israeli, titi nwọn fi pari.

Deu 31