19. Njẹ nisisiyi, kọwe orin yi fun ara nyin, ki ẹ fi kọ́ awọn ọmọ Israeli: fi i si wọn li ẹnu, ki orin yi ki o le ma jẹ́ ẹrí fun mi si awọn ọmọ Israeli.
20. Nitoripe nigbati emi ba mú wọn wá si ilẹ na, ti mo bura fun awọn baba wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; ti nwọn ba si jẹ ajẹyo tán, ti nwọn si sanra; nigbana ni nwọn o yipada si oriṣa, nwọn a si ma sìn wọn, nwọn a si kẹ́gan mi, nwọn a si dà majẹmu mi.
21. Yio si ṣe, nigbati ibi pupọ̀ ati iyọnu ba bá wọn, ki orin yi ki o jẹri tì wọn bi ẹlẹri; nitoripe a ki yio gbagbé rẹ̀ lati ẹnu awọn ọmọ wọn: nitori mo mọ̀ ìro inu wọn, ti nwọn nrò, ani nisisiyi, ki emi ki o to mú wọn wá sinu ilẹ na ti mo bura si.
22. Nitorina ni Mose ṣe kọwe orin yi li ọjọ́ na gan, o si fi kọ́ awọn ọmọ Israeli.
23. O si paṣẹ fun Joṣua ọmọ Nuni, o si wipe, Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio mú awọn ọmọ Israeli lọ sinu ilẹ na ti mo bura fun wọn: Emi o si wà pẹlu rẹ.
24. O si ṣe, nigbati Mose pari kikọ ọ̀rọ ofin yi tán sinu iwé, titi nwọn fi pari,
25. Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ti nrù apoti majẹmu OLUWA, wipe,
26. Gbà iwé ofin yi, ki o si fi i sapakan apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o ma wà nibẹ̀ fun ẹrí si ọ.
27. Nitoripe mo mọ̀ ọ̀tẹ rẹ, ati lile ọrùn rẹ: kiyesi i, nigbati emi wà lãye sibẹ̀ pẹlu nyin li oni, ọlọtẹ̀ li ẹnyin ti nṣe si OLUWA; melomelo si ni lẹhin ikú mi?
28. Pè gbogbo awọn àgba ẹ̀ya nyin jọ sọdọ mi, ati awọn ijoye nyin, ki emi ki o le sọ ọ̀rọ wọnyi li etí wọn ki emi ki o si pè ọrun ati aiye jẹri tì wọn.