Deu 30:4-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Bi a ba si lé ẹni rẹ kan lọ si ìha opin ọrun, lati ibẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio kó ọ jọ, lati ibẹ̀ ni yio si mú ọ wá:

5. OLUWA Ọlọrun rẹ yio si mú ọ wá sinu ilẹ na ti awọn baba rẹ ti ní, iwọ o si ní i; on o si ṣe ọ li ore, yio si mu ọ bisi i jù awọn baba rẹ lọ.

6. OLUWA Ọlọrun rẹ yio si kọ àiya rẹ nilà, ati àiya irú-ọmọ rẹ, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, ki iwọ ki o le yè.

7. OLUWA Ọlọrun rẹ yio si fi gbogbo egún wọnyi lé awọn ọtá rẹ lori, ati lori awọn ti o korira rẹ, ti nṣe inunibini si ọ.

8. Iwọ o si pada, iwọ o si gbà ohùn OLUWA gbọ́, iwọ o si ma ṣe gbogbo ofin rẹ̀ ti mo palaṣẹ fun ọ li oni.

9. OLUWA Ọlọrun rẹ yio si sọ ọ di pupọ̀ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, fun rere: nitoriti OLUWA yio pada wa yọ̀ sori rẹ fun rere, bi o ti yọ̀ sori awọn baba rẹ:

Deu 30