Deu 3:27-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Gùn ori òke Pisga lọ, ki o si gbé oju rẹ soke si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù, ati si ìha ìla-õrùn, ki o si fi oju rẹ wò o: nitoripe iwọ ki yio gòke Jordani yi.

28. Ṣugbọn fi aṣẹ fun Joṣua, ki o si gbà a niyanju, ki o si mu u li ọkàn le: nitoripe on ni yio gòke lọ niwaju awọn enia yi, on o si mu wọn ni ilẹ na ti iwọ o ri.

29. Awa si joko li afonifoji ti o kọjusi Beti-peori.

Deu 3