20. Titi OLUWA o fi fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti fi fun ẹnyin, ati titi awọn pẹlu yio fi ní ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun wọn loke Jordani: nigbana li ẹnyin o pada, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ti mo ti fi fun nyin.
21. Emi si fi aṣẹ fun Joṣua ni ìgbana, wipe, Oju rẹ ti ri gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si awọn ọba mejeji wọnyi: bẹ̃ni OLUWA yio ṣe si gbogbo ilẹ-ọba nibiti iwọ o kọja.
22. Ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru wọn: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on ni yio jà fun nyin.
23. Emi si bẹ̀ OLUWA ni ìgba na, wipe,
24. OLUWA Ọlọrun, iwọ ti bẹ̀rẹsi fi titobi rẹ hàn fun iranṣẹ rẹ, ati ọwọ́ agbara rẹ: nitoripe Ọlọrun wo ni li ọrun ati li aiye, ti o le ṣe gẹgẹ bi iṣẹ rẹ, ati gẹgẹ bi iṣẹ-agbara rẹ?
25. Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o kọja si ìha keji, ki emi si ri ilẹ rere na ti mbẹ loke Jordani, òke daradara nì, ati Lebanoni.
26. Ṣugbọn OLUWA binu si mi nitori nyin, kò si gbọ́ ti emi: OLUWA si wi fun mi pe, O to gẹ; má tun bá mi sọ ọ̀rọ yi mọ́.
27. Gùn ori òke Pisga lọ, ki o si gbé oju rẹ soke si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù, ati si ìha ìla-õrùn, ki o si fi oju rẹ wò o: nitoripe iwọ ki yio gòke Jordani yi.
28. Ṣugbọn fi aṣẹ fun Joṣua, ki o si gbà a niyanju, ki o si mu u li ọkàn le: nitoripe on ni yio gòke lọ niwaju awọn enia yi, on o si mu wọn ni ilẹ na ti iwọ o ri.