8. Awa si gbà ilẹ wọn, a si fi i fun awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse ni iní.
9. Nitorina, ẹ pa ọ̀rọ majẹmu yi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn, ki ẹnyin ki o le ma ri ire ninu ohun gbogbo ti ẹnyin nṣe.
10. Gbogbo nyin li o duro li oni niwaju OLUWA Ọlọrun nyin; awọn olori nyin, awọn ẹ̀ya nyin, awọn àgba nyin, ati awọn ijoye nyin, ani gbogbo awọn ọkunrin Israeli,
11. Awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, awọn aya nyin, ati alejò rẹ, ti mbẹ lãrin ibudó rẹ, lati aṣẹgi rẹ dé apọnmi rẹ:
12. Ki iwọ ki o le wọ̀ inu majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ibura rẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ ṣe li oni:
13. Ki o le fi idi rẹ kalẹ li oni li enia kan fun ara rẹ̀, ati ki on ki o le ma ṣe Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ fun ọ, ati bi o ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu.
14. Ki si iṣe ẹnyin nikan ni mo bá ṣe majẹmu yi ati ibura yi;
15. Ṣugbọn ẹniti o bá wa duro nihin li oni niwaju OLUWA Ọlọrun wa, ẹniti kò sí nihin pẹlu wa li oni:
16. (Nitoripe ẹnyin mọ̀ bi awa ti gbé ilẹ Egipti; ati bi awa ti kọja lãrin orilẹ-ède ti ẹnyin là kọja;
17. Ẹnyin si ti ri ohun irira wọn, ati ere wọn, igi ati okuta, fadakà ati wurà, ti o wà lãrin wọn.)
18. Ki ẹnikẹni ki o má ba wà ninu nyin, ọkunrin, tabi obinrin, tabi idile, tabi ẹ̀ya, ti àiya rẹ̀ ṣí kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun wa li oni, lati lọ isìn oriṣa awọn orilẹ-ède wọnyi; ki gbòngbo ti nyọ orõro ati iwọ, ki o má ba wà ninu nyin;
19. Yio si ṣe, nigbati o ba gbọ́ ọ̀rọ egún yi, ti o sure fun ara rẹ̀ ninu àiya rẹ̀, wipe, Emi o ní alafia, bi emi tilẹ nrìn ninu agídi ọkàn mi, lati run tutù pẹlu gbigbẹ:
20. OLUWA ki yio darijì i, ṣugbọn nigbana ni ibinu OLUWA ati owú rẹ̀ yio gbona si ọkunrin na, ati gbogbo egún wọnyi ti a kọ sinu iwé yi ni yio bà lé e, OLUWA yio si nù orukọ rẹ̀ kuro labẹ ọrun.