Deu 26:5-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Iwọ o si dahùn iwọ o si wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Ara Siria kan, ti o nṣegbé ni baba mi, on si sọkalẹ lọ si Egipti, o si ṣe atipo nibẹ̀, ti on ti enia diẹ; nibẹ̀ li o si di orilẹ-ède nla, alagbara, ati pupọ̀:

6. Awọn ara Egipti si hùwabuburu si wa, nwọn si pọn wa loju, nwọn si dì ẹrù wuwo rù wa:

7. Awa si kepè OLUWA, Ọlọrun awọn baba wa, OLUWA si gbọ́ ohùn wa, o si wò ipọnju wa, ati lãlã wa, ati inira wa:

8. OLUWA si mú wa lati Egipti jade wá pẹlu ọwọ́ agbara, ati apa ninà, ati pẹlu ẹrù nla, ati pẹlu iṣẹ-àmi, ati pẹlu iṣẹ-iyanu:

9. O si mú wa dé ihin yi, o si fi ilẹ yi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.

10. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, emi mú akọ́so ilẹ na wa, ti iwọ, OLUWA, fi fun mi. Ki iwọ ki o si gbé e kalẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma foribalẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ:

11. Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ohun rere gbogbo, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ati fun ara ile rẹ, iwọ, ati ọmọ Lefi, ati alejò ti mbẹ lãrin rẹ.

12. Nigbati iwọ ba da idamẹwa asunkun rẹ tán li ọdún kẹta, ti iṣe ọdún idamẹwa, ti iwọ si fi fun ọmọ Lefi, alejò, alainibaba, ati opó, ki nwọn ki o ma jẹ li ẹnubode rẹ, ki nwọn si yó;

13. Nigbana ni ki iwọ ki o wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Emi ti mú ohun mimọ́ kuro ninu ile mi, mo si ti fi wọn fun ọmọ Lefi, ati fun alejò, ati fun alainibaba, ati fun opó, gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ rẹ ti iwọ ti pa fun mi: emi kò re aṣẹ rẹ kọja, bẹ̃li emi kò gbagbé wọn:

14. Emi kò jẹ ninu rẹ̀ ninu ọ̀fọ mi, bẹ̃li emi kò mú kuro ninu rẹ̀ fun ohun aimọ́ kan, bẹ̃li emi kò mú ninu rẹ̀ fun okú: ṣugbọn emi ti gbà ohùn OLUWA Ọlọrun mi gbọ́, emi si ti ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ palaṣẹ fun mi.

Deu 26