Wò ilẹ lati ibujoko mimọ́ rẹ wá, lati ọrun wá, ki o si busi i fun Israeli enia rẹ, ati fun ilẹ na ti iwọ fi fun wa, bi iwọ ti bura fun awọn baba wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.