6. Yio si ṣe, akọ́bi ọmọ ti o bi ki o rọpò li orukọ arakunrin rẹ̀ ti o kú, ki orukọ rẹ̀ ki o má ba parẹ́ ni Israeli.
7. Bi ọkunrin na kò ba si fẹ́ lati mú aya arakunrin rẹ̀, njẹ ki aya arakunrin rẹ̀ ki o gòke lọ si ẹnubode tọ̀ awọn àgba lọ, ki o si wipe, Arakunrin ọkọ mi kọ̀ lati gbé orukọ arakunrin rẹ̀ ró ni Israeli, on kò fẹ́ ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ mi.
8. Nigbana ni awọn àgba ilu rẹ̀ yio pè e, nwọn a si sọ fun u: bi o ba si duro si i, ti o si wipe, Emi kò fẹ́ lati mú u;
9. Nigbana ni aya arakunrin rẹ̀ yio tọ̀ ọ wá niwaju awọn àgba na, on a si tú bàta rẹ̀ kuro li ẹsẹ̀ rẹ̀, a si tutọ si i li oju; a si dahùn, a si wipe, Bayi ni ki a ma ṣe si ọkunrin na ti kò fẹ́ ró ile arakunrin rẹ̀.
10. A o si ma pè orukọ rẹ̀ ni Israeli pe, Ile ẹniti a tú bàta rẹ̀.
11. Bi awọn ọkunrin ba mbá ara wọn jà, ti aya ọkan ba si sunmọtosi lati gbà ọkọ rẹ̀ lọwọ ẹniti o kọlù u, ti on si nawọ́ rẹ̀, ti o si di i mú li abẹ:
12. Nigbana ni ki iwọ ki o ke ọwọ́ rẹ̀ kuro, ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u.
13. Iwọ kò gbọdọ ní onirũru ìwọn ninu àpo rẹ, nla ati kekere.
14. Iwọ kò gbọdọ ní onirũru òṣuwọn ninu ile rẹ, nla ati kekere.
15. Iwọn pipé ati dẽde ni ki iwọ ki o ní; òṣuwọn pipé ati dẽde ni ki iwọ ki o ní: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
16. Nitoripe gbogbo ẹniti nṣe wọnyi, ati gbogbo ẹniti nṣe aiṣododo, irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ.
17. Ranti ohun ti Amaleki ṣe si ọ li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti ilẹ Egipti jade wá;
18. Bi o ti pade rẹ li ọ̀na, ti o si kọlù awọn ti o kẹhin rẹ, ani gbogbo awọn ti o ṣe alailera lẹhin rẹ, nigbati ãrẹ mú ọ tán, ti agara si dá ọ; ti on kò si bẹ̀ru Ọlọrun.