1. BI gbolohùn-asọ̀ kan ba wà lãrin enia, ti nwọn si wá si ibi idajọ, ti nwọn si dajọ wọn; nigbana ni ki nwọn ki o fi are fun alare, ki nwọn ki o si fi ẹbi fun ẹlẹbi;
2. Yio si ṣe, bi ẹlẹbi na ba yẹ lati nà, ki onidajọ na ki o da a dọbalẹ, ki o si mu ki a nà a ni iye kan li oju on, gẹgẹ bi ìwabuburu rẹ̀.