15. Iwọ kò gbọdọ fà ẹrú ti o sá lati ọdọ oluwa rẹ̀ tọ̀ ọ wá lé oluwa rẹ̀ lọwọ:
16. Ki on ki o bá ọ joko, ani lãrin nyin, ni ibi ti on o yàn ninu ọkan ni ibode rẹ, ti o wù u jù: ki iwọ ki o máṣe ni i lara.
17. Ki àgbere ki o máṣe sí ninu awọn ọmọbinrin Israeli, tabi oníwà-sodomu ninu awọn ọmọkunrin Israeli.
18. Iwọ kò gbọdọ mú owo ọ̀ya àgbere, tabi owo ajá, wá sinu ile OLUWA Ọlọrun rẹ fun ẹjẹ́kẹjẹ: nitoripe irira ni, ani awọn mejeji si OLUWA Ọlọrun rẹ.
19. Iwọ kò gbọdọ wín arakunrin rẹ fun elé; elé owo, elé onjẹ, elé ohun kan ti a wínni li elé:
20. Alejò ni ki iwọ ki o ma wín fun elé; ṣugbọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o máṣe win fun elé: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma bukún ọ ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé, ni ilẹ na nibiti iwọ nlọ lati gbà a.