1. ẸNITI a fọ ni kóro, tabi ti a ke ẹ̀ya ìkọkọ rẹ̀ kuro, ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA.
2. Ọmọ-àle ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA; ani dé iran kẹwa enia rẹ̀ kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA.
3. Ọmọ Ammoni tabi ọmọ Moabu kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA; ani dé iran kẹwa enia wọn kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA lailai:
4. Nitoriti nwọn kò fi omi pẹlu onjẹ pade nyin li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti Egipti jade wá; ati nitoriti nwọn bẹ̀wẹ Balaamu ọmọ Beori ara Petori ti Mesopotamia si ọ, lati fi ọ bú.
5. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun rẹ kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; OLUWA Ọlọrun rẹ si yi egún na pada si ibukún fun ọ, nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ fẹ́ ọ.
6. Iwọ kò gbọdọ wá alafia wọn tabi ire wọn li ọjọ́ rẹ gbogbo lailai.
7. Iwọ kò gbọdọ korira ara Edomu kan; nitoripe arakunrin rẹ ni iṣe: iwọ kò gbọdọ korira ara Egipti kan; nitoripe iwọ ti ṣe alejò ni ilẹ rẹ̀.
8. Awọn ọmọ ti a bi fun wọn yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA ni iran kẹta wọn.
9. Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o pa ara rẹ mọ́ kuro ninu ohun buburu gbogbo.