1. IWỌ kò gbọdọ ri akọ-malu tabi agutan arakunrin rẹ ti o nṣako, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn; bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o mú wọn pada tọ̀ arakunrin rẹ wá.
2. Bi arakunrin rẹ kò ba si sí nitosi rẹ, tabi bi iwọ kò ba mọ̀ ọ, njẹ ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ, ki o si wà lọdọ rẹ titi arakunrin rẹ yio fi wá a wá, ki iwọ ki o si fun u pada.
3. Bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o si ṣe si gbogbo ohun ninù arakunrin rẹ, ti o nù lọwọ rẹ̀, ti iwọ si ri: ki iwọ ki o máṣe mú oju rẹ kuro.